BECE Yoruba Language 2023 Objective — Question 1
Question 1 of 120 from the Basic Education Certificate Examination (Junior WAEC) (BECE) Yoruba Language 2023 Objective paper, with the correct answer and a full explanation.
Advertisement
SECTION 1 (ÌPÍN-KÌN-ÍN-NÍ) ÀKÀYÉ KÌN-ÍN-NÍ Ka àyọkà ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé wọn. Tóyèṣe àti Mákindé jẹ́ ọ̀rẹ́, kíláàsì kejì ni àwọn méjèèjì wà ní ilé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì kékeré. Ọmọ tó múra sí iṣẹ́ ni Mákindé. Bí ó ti jẹ́ ọkùnrin, kò sí iṣẹ́ ilé tí ìyá rẹ̀ kò fi kọ́ ọ. Ó máa ń gbá ilẹ̀, ó ń fọ abọ́ àti aṣọ, ó ń nu ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni ó mọ oúnjẹ sè níwọ̀nba. Tóyèṣe ní tirẹ̀ le ju ìsọ́ ìdí lọ, ṣe ni ó máa ń yọ́rí bọ́rọ́ tí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ bá ti délẹ̀. Ẹkún ni ó máa fi ń gba ara rẹ̀ sílẹ̀ ní irú àsìkò bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ gan an ti sú àwọn òbí rẹ̀. Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe iṣẹ́ oko títí di aago méwàá àárọ̀, Tóyèṣe yọ́ pòórá, ó gbọ̀nà oko kan tó wà lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ wọn lọ. Bí ó ṣe fa ẹ̀ka igi ọsàn tó wà nítòsí rẹ̀ láti ká ọsàn ni ejò sébé tó wà lára ẹ̀ka igi yìí ṣán an lọ́wọ́. Tóyèṣe fi igbe ta, ọpẹ́lọpẹ́ bàbá ọdẹ kan tí ó ń kọjá lọ tí ó fún un ní òògùn aporó ejò. Ọ̀rọ̀ yìí bí ọga àgbà ilé-ẹ̀kọ́ yìí nínú; ó ránṣẹ́ pe àwọn òbí rẹ̀ láti kì í nílọ̀, wọ́n sì fún un ní ìwé ìgbélé fún ọ̀sẹ̀ méjì. Dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí Tóyèṣe jẹ́ ______ Mákindé
- A. àbúrò
- B. ẹ̀gbọ́n
- C. ọ̀gá
- D. ọ̀rẹ́Correct
- E. ọ̀tá
Explanation
Àyọkà sọ pé Tóyèṣe àti Mákindé jẹ́ ọ̀rẹ́.
Advertisement
Sign up free to unlock
- Score tracking
- Practice history
- Saved questions
- Progress dashboard
- Personalized sessions
- Weak-topic breakdown
…and/or go further with premium services and No Ads.