All 120 questions from the Basic Education Certificate Examination (Junior WAEC) (BECE) Yoruba Language 2023 Objective paper, with the correct answer and a full explanation for each. Free, no signup needed.
SECTION 1 (ÌPÍN-KÌN-ÍN-NÍ)
ÀKÀYÉ KÌN-ÍN-NÍ
Ka àyọkà ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé wọn.
Tóyèṣe àti Mákindé jẹ́ ọ̀rẹ́, kíláàsì kejì ni àwọn méjèèjì wà ní ilé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì kékeré. Ọmọ tó múra sí iṣẹ́ ni Mákindé. Bí ó ti jẹ́ ọkùnrin, kò sí iṣẹ́ ilé tí ìyá rẹ̀ kò fi kọ́ ọ. Ó máa ń gbá ilẹ̀, ó ń fọ abọ́ àti aṣọ, ó ń nu ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni ó mọ oúnjẹ sè níwọ̀nba. Tóyèṣe ní tirẹ̀ le ju ìsọ́ ìdí lọ, ṣe ni ó máa ń yọ́rí bọ́rọ́ tí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ bá ti délẹ̀. Ẹkún ni ó máa fi ń gba ara rẹ̀ sílẹ̀ ní irú àsìkò bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ gan an ti sú àwọn òbí rẹ̀.
Ní ọjọ́ ìṣẹ́gun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe iṣẹ́ oko títí di aago méwàá àárọ̀, Tóyèṣe yọ́ pòórá, ó gbọ̀nà oko kan tó wà lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ wọn lọ. Bí ó ṣe fa ẹ̀ka igi ọsàn tó wà nítòsí rẹ̀ láti ká ọsàn ni ejò sébé tó wà lára ẹ̀ka igi yìí ṣán an lọ́wọ́. Tóyèṣe fi igbe ta, ọpẹ́lọpẹ́ bàbá ọdẹ kan tí ó ń kọjá lọ tí ó fún un ní òògùn aporó ejò. Ọ̀rọ̀ yìí bí ọga àgbà ilé-ẹ̀kọ́ yìí nínú; ó ránṣẹ́ pe àwọn òbí rẹ̀ láti kì í nílọ̀, wọ́n sì fún un ní ìwé ìgbélé fún ọ̀sẹ̀ méjì.
Dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí
Tóyèṣe jẹ́ ______ Mákindé
A. àbúròB. ẹ̀gbọ́nC. ọ̀gáD. ọ̀rẹ́Correct E. ọ̀táExplanation Àyọkà sọ pé Tóyèṣe àti Mákindé jẹ́ ọ̀rẹ́.
Tọ́ka sí iṣẹ́ tí Mákindé kìí ṣe nínú ìwọ̀nyí.
A. Abọ́ fífọ̀B. Aṣọ fífọ̀C. Ilẹ̀ gbígbáD. Ilẹ̀ nínùE. Omi pípọnCorrect Explanation Àyọkà kò dárúkọ omi pípọn; Mákindé ń gbá ilẹ̀, ń fọ abọ́ àti aṣọ, ó ń nu ilẹ̀.
Tóyèṣe sá kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ nítorí
A. àwọn olùkọ́ ń yan iṣẹ́ lódì.B. ebi ń pa á.C. kó má baà ṣe ìdánwò.D. kó má baà ṣiṣẹ́ oko.Correct E. wọ́n ránṣẹ́ pè é ní oko.Explanation Tóyèṣe kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ oko, ó sì yọ́ lọ.
Kín ni ó ṣẹlẹ̀ sí Tóyèṣe níbi tó sá lọ?
A. Ejò bù ú jẹCorrect B. Ẹ̀gún gún un lẹ́sẹ̀C. Ó jábọ́ lórí igiD. Ó pàdé iwinE. Ó tẹsẹ̀ bọ tàkútéExplanation Ejò ṣán an lọ́wọ́.
Àkọlé tó bá àkàyé yìí mu jùlọ ni
A. Eré Ìmẹ́lẹ́ ṢíṣeB. Iṣẹ́ Àgbẹ̀C. Oore Ló PéD. Ọ̀rẹ́ MéjìE. Wàhálà Ilé Ẹ̀kọ́Correct Explanation Àyọkà jẹ́ nípa wàhálà tí Tóyèṣe fà ní ilé ẹ̀kọ́.
SECTION 2 (ÌPÍN KEJÌ)
ÀKÀYÉ KEJÌ
Afọlábí: Mo mà gbádùn ọbẹ̀ elégédé tí mo fi jẹ iyán ọ̀sán yìí gan an o.
Àkànkẹ́: Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pa á, baálé mi.
Afọlábí: Bẹ́ẹ̀ ni tìrẹ rí, aya rere lóòdẹ̀ ọkọ.
Àkànkẹ́: Mo rí ìwé ọmọ yín ní ọ̀sán yìí, ó ní kí n kí i yín.
Afọlábí: Ṣé àlàáfíà ni ó wà? Nítòótọ́ obìnrin ni Ẹ̀sítà, ṣùgbọ́n ṣáṣà ọmọkùnrin ló lè ṣe ohun tó ń ṣe yìí, lẹ́nu ọ̀sẹ̀ mẹ́rin tí ó padà sí ilé-ẹ̀kọ́, lẹ́tà rẹ̀ ti di méjì.
Àkànkẹ́: Ọmọbìnrin dára lóòótọ́ ṣùgbọ́n ọmọkùnrin ló dára jù. Ọmọbìnrin le ṣe aájò nígbà tó bá wà ní wúndíá, tó bá ti délé ọkọ tán, “akẹ̀yìnsí abiyamọ kò gbẹ́kùn ní ọ̀rọ̀ wọn.”
Afọlábí: Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọkùnrin ni ọ̀nà wọn pọ̀; tí wọ́n kìí rójú gbọ́ ti àwọn òbí wọn ṣùgbọ́n kò sì bí ojú ṣe lè dí tó, tí ọmọbìnrin kò ní ránti òbí rẹ̀.
Àkànkẹ́: Ṣebí obìnrin ni èmi náà, òní ti ìyá ọkọ, ọ̀la ti bàbá ọkọ, ọ̀tunla ti orogún ilé, kìí jẹ́ kí ọmọbìnrin rí ààyè mójútó òbí rẹ̀. Èyí ni mo fi sọ pé, ọmọkùnrin wúlò fún òbí ju ọmọbìnrin lọ.
Afọlábí: Gbogbo ohun tí ọkùnrin lè ṣe náà ni obìnrin lè ṣe, kí Ọlọ́run fún wa ní aláàánú ọmọ ni kókó àdúrà.
Àkànkẹ́: Àṣẹ! àmọ́ ọmọkùnrin ni èmi ń fẹ́, kí Ọlọ́run fún mi lọ́mọkùnrin pẹ̀lú Ẹ̀sítà, kí wọ́n lè di méjì sími lọ́wọ́.
Afọlábí: Àmín, ká ẹni wọlé kúrò lábẹ́ igi ọdán ká lọ sùn. Àdúrà rẹ ti gbà.
Àkókò wo ni ìtàkurọ̀sọ yìí wáyé?
A. Alẹ́B. Ìyálẹ̀taC. Òwúrọ̀ kùtùD. Ọgànjọ́ òruE. Ọ̀sánCorrect Explanation Afọlábí sọ pé wọ́n jẹ iyán ní ọ̀sán yìí.
Ó tó ọ̀sẹ̀ mélòó tí Ẹ̀sítà ti padà sí ilé-ẹ̀kọ́? Ọ̀sẹ̀
A. kanB. méjìC. mẹ́taD. mẹ́rinCorrect E. márùn únExplanation Afọlábí sọ pé lẹ́nu ọ̀sẹ̀ mẹ́rin ni.
Àárín àwọn wo ni ìtàkurọ̀sọ yìí ti wáyé?
A. Àkànkẹ́ àti Afọlábí.Correct B. Ẹ̀sítà àti AfọlábíC. Ẹ̀sítà àti Àkànkẹ́D. Òbí àti olùkọ́.E. Olùkọ́ àti akẹ́ẹ̀kọ́.Explanation Àkànkẹ́ àti Afọlábí ni ọkọ àti aya tó ń sọ̀rọ̀.
Kín ni ó bí ìtàkurọ̀sọ yìí?
A. Èsì ìdánwò Ẹ̀sítà tí ó ti fakọyọ.B. Ẹ̀kọ́ ìwé Ẹ̀sítà tí ó jẹ òbí rẹ̀ lógún.C. Ìyá Ẹ̀sítà kò fẹ́ràn rẹ̀.D. Iyán ọ̀sán tí wọ́n jẹ.E. Lẹ́tà Ẹ̀sítà tí wọ́n rí gbà.Correct Explanation Afọlábí sọ pé Ẹ̀sítà kọ lẹ́tà méjì, èyí sì bí ọ̀rọ̀ náà.
Àkọlé wo ló bá àkàyé yìí mu jùlọ?
A. Àìfàání Ọmọkùnrin Àti Obìnrin.B. Àrólé Ọmọ.Correct C. Aya Rere Lóòdè Ọkọ.D. Obìnrin Wúlò Ju Ọkùnrin Lọ.E. Ọkùnrin Dára Nílé Ju Obìnrin Lọ.Explanation Wọ́n ń jíròrò ọmọkùnrin gẹ́gẹ́ bí àrólé.
SECTION 3 (ÌPÍN KẸTA)
ÀRÒKỌ KÍKỌ
Èwo ló yẹ kó ṣaájú nínú ìgbésẹ̀ àròkọ kíkọ?
A. ÌfááràCorrect B. ÌgúnlèC. Ìlapa èròD. Ìpínrọ̀E. Orí ọ̀rọ̀Explanation Ìfáárà ni ó ṣaájú nínú àròkọ.
Tí kò bá sí ______ àròkọ kò lè wáyé.
A. èdèCorrect B. ewìC. èfèD. ìlùE. orinExplanation Láì sí èdè, a kò lè kọ àròkọ.
Èwo ni kò sí lára orísìí àròkọ tí ó wà nínú èdè Yorùbá?
A. AlálàyéB. AlárìíyànjiyànC. Alárọ̀yéD. Onílẹ́tàCorrect E. OníròyìnExplanation Onílẹ́tà kì í ṣe orísìí àròkọ.
‘Bí Mo Bá Di Gómìnà Ìpínlẹ̀ Mi’ jẹ mọ́ àròkọ
A. alálàyéB. alápèjúweCorrect C. alárìíyànjiyànD. asọ̀tànE. oníròyìnExplanation Àkọlé yìí ń pè fún àpèjúwe ohun tí olùkọ̀wé yóò ṣe.
Èwo ni kò wúlò nínú kíkọ àròkọ nínú èdè Yorùbá?
A. Àwòrán yíyàCorrect B. ÌfááràC. ÌgúnlèD. Ìlapa èròE. Ìpínrọ̀Explanation Àwòrán yíyà kì í ṣe apá àròkọ.
ÈTÒ ÌRÓ
Fáwẹ́lì àìránmúpè Yorùbá jẹ́
A. méjìB. mẹ́taC. mẹ́rinD. márùn-únE. méjeCorrect Explanation Fáwẹ́lì àìránmúpè méje ni: a, e, ẹ, i, o, ọ, u.
Kọ́ńsónántì ‘f’ jẹ́ ìró
A. afàfàsépèB. afàjàpèC. afèrígipèCorrect D. afẹ́tẹ̀pèE. afẹyínfẹ́tẹ̀pèExplanation Ètè ìsàlẹ̀ àti eyín òkè ni a fi pe ‘f’: afèrígipè.
Ìró /o/ jẹ́ àpẹẹrẹ fáwẹ́lì
A. àhánupèB. àránmúpèC. èyìnCorrect D. ìwájúE. pẹ̀rẹ̀sẹ̀Explanation /o/ jẹ́ fáwẹ́lì èyìn.
Fáwẹ́lì ìwájú, èbádò, àyanudìẹ̀pè ni
A. /a/B. /e/C. /ɛ/Correct D. /i/E. /o/Explanation /ɛ/ (ẹ) jẹ́ fáwẹ́lì ìwájú tó ṣí ní ààrin.
Èwo ni èyà ara tí a fi ń gbé ìró jáde nínú àwọn wọ̀nyí?
A. Àgbọ̀nCorrect B. ApáC. ÈrìgìD. EtíE. OjúExplanation Àgbọ̀n jẹ́ ara àwọn èyà ara ìsọ̀rọ̀.
Kọ́ńsónántì kẹjọ nínú álífábẹ́ẹ̀tì Yorùbá ni
A. gB. gbC. kCorrect D. nE. yExplanation Ìtò: b, d, f, g, gb, h, j, k; nítorí náà ‘k’.
Kọ́ńsónántì àránmúpè aṣesílébù jẹ́
A. méjìCorrect B. mẹ́taC. mẹ́rinD. márùn únE. mẹ́fàExplanation M àti n ni kọ́ńsónántì aṣesílébù.
Kọ́ńsónántì-‘m’ jẹ́ ìró
A. afàjàpèB. afèrígipèC. afẹ́tẹ̀pèCorrect D. aréhọ́nE. àsèsíExplanation ‘m’ ni a fi ètè méjèèjì pè: afẹ́tẹ̀pè.
Mélòó ni ìró álífábẹ́ẹ̀tì Yorùbá?
A. MéjìláB. Mẹ́tàdínlógúnC. Mọ́kànlélógúnD. Márùndínlọ́gbọ̀nCorrect E. Méjìdínlógbọ̀nExplanation Álífábẹ́ẹ̀tì Yorùbá ní lẹ́tà márùndínlọ́gbọ̀n (25).
Àpẹẹrẹ fáwẹ́lì àránmúpè Yorùbá ni
A. /e/B. /n/C. /o/D. /u/E. /ũ/Correct Explanation Fáwẹ́lì àránmúpè ni /ũ/.
GÍRÁMÀ
‘Ojú ọjọ́ mọ́lẹ̀ rokoso.’
Èwo ni ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé nínú gbólóhùn yìí?
A. Mọ́lẹ̀B. Mọ́lẹ̀ rokosoC. OjúD. Ojú ọjọ́E. RokosoCorrect Explanation Rokoso ni ọ̀rọ̀ àpọ́nlé (adverb) tó ń ṣàpèjúwe ‘mọ́lẹ̀’.
Èwo ni ó jẹ́ ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ẹnìkẹta ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà?
A. OB. RẹC. WaD. Wọ́nCorrect E. YínExplanation ‘Wọ́n’ ni arọ́pò orúkọ ẹnìkẹta ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà.
‘Èmi ni ọkọ Ṣadé.’
‘Èmi’ jẹ́ ọ̀rọ̀
A. àpèjúweB. àpọ́nléC. arọ́pò afarajorúkọD. arọ́pò orúkọCorrect E. ìṣeExplanation ‘Èmi’ dúró fún orúkọ ẹni; arọ́pò orúkọ ni.
Ọ̀rọ̀ ìṣe ẹlẹ́là ni
A. dúróCorrect B. gbàgbọ́C. gbúròóD. jádeE. wàhálàExplanation Ọ̀rọ̀ ìṣe ẹlẹ́là ni èyí tí kò ní àbọ̀: dúró.
‘Ọmọ pupa náà ti lọ’, ‘náà’ jẹ́ ẹyán
A. ajorúkọB. aṣàpèjúweC. aṣàfihànCorrect D. aṣòǹkàE. oníbààtanExplanation ‘Náà’ ń fi ọmọ náà hàn; aṣàfihàn ni.
‘Ọmọ náà lọ sí Ìbàdàn lánàá’, ‘sí’ jẹ́ ọ̀rọ̀
A. àpèjúweB. àpọ́nléC. arọ́pò orúkọD. àsopọ̀E. atọ́kùnCorrect Explanation ‘Sí’ jẹ́ atọ́kùn (preposition).
Ọ̀rọ̀ orúkọ tí a ṣẹ̀dá ni
A. ìfẹ́Correct B. iléC. ilùD. ìwéE. ọbẹ̀Explanation Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ tí a ṣẹ̀dá láti inú ọ̀rọ̀ ìṣe ‘fẹ́’.
Èwo ni kìí ṣe gbólóhùn alákànpọ̀?
A. Ìgè jẹ àmàlà, ó tún mu omi síi.B. Mo ti bọ ẹran jẹ tán, kí Olú tó dé.Correct C. Olú wá, ó sì bámi.D. Ó rí wọn ṣùgbọ́n kò mọ wọ́n.E. Ó se ọbẹ̀ náà dáradára ṣùgbọ́n kò rí ẹni bá a jẹ ẹ́.Explanation Gbólóhùn B ní ọ̀rọ̀ atọ́ka (kí ... tó) tó mú un jẹ́ aláfarahàn, kì í ṣe alákànpọ̀.
‘Olú àti Ìdòwú lọ sí Ìbàdàn.’
Èwo ni ọ̀rọ̀ àsopọ̀ nínú gbólóhùn yìí?
A. ÀtiCorrect B. ÌbàdànC. LọD. OlúE. SíExplanation ‘Àti’ so Olú àti Ìdòwú pọ̀.
‘Bàbá ra àgbò funfun.’
Tọ́ka sí ọ̀rọ̀ àpèjúwe nínú gbólóhùn yìí.
A. Àgbò funfunB. BàbáC. FunfunCorrect D. RaE. Ra àgbòExplanation ‘Funfun’ ṣàpèjúwe àgbò.
‘Ó fẹ́ràn oúnjẹ aládùn jù.’
Ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ inú gbólóhùn yìí ni
A. aládùnB. fẹ́rànC. jùD. óCorrect E. oúnjẹExplanation ‘Ó’ jẹ́ arọ́pò orúkọ ẹnìkẹta.
‘Mọ́tò aláwọ̀ pupa ni mo fẹ́.’
Èwo ni ọ̀rọ̀ aṣàpèjúwe nínú gbólóhùn yìí?
A. Fẹ́B. MoC. Mọ́tòD. NiE. PupaCorrect Explanation ‘Pupa’ ṣàpèjúwe àwọ̀ mọ́tò.
‘Àgbàdo ń ta pàúpàù’, ‘pàúpàù’ jẹ́ ọ̀rọ̀
A. àpèjúweB. àpọ́nléCorrect C. atọ́kùnD. ìṣeE. orúkọExplanation ‘Pàúpàù’ ṣàlàyé bí àgbàdo ṣe ń ta; ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni.
Èwo nínú àwọn wọ̀nyí ni kò lè wà ní ipò olùwà tàbí àbọ̀?
A. AdétúnjíB. ÀdìóC. DìdeCorrect D. ÌwọE. TádéExplanation ‘Dìde’ jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe, kò lè jẹ́ olùwà tàbí àbọ̀ lásán.
‘Olùkọ́ wa bá Àjàó wí.’ Ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ipò àbọ̀ ni
A. ÀjàóCorrect B. báC. olùkọ́D. waE. wíExplanation ‘Àjàó’ ni ẹni tí wọ́n bá wí.
Èwo ni kì í ṣe arọ́pò afarajorúkọ?
A. ÀwaB. ÀwọnC. ẸyinD. ÒunE. WọnCorrect Explanation ‘Wọn’ jẹ́ arọ́pò orúkọ oní kúkúrú, kì í ṣe afarajorúkọ.
“Olùkọ́ ti Èkó lọ sí Ọyọ́”, ‘ti’ jẹ́ ọ̀rọ̀
A. àpèjúweB. àpọ́nléC. aṣàfihànD. atọ́kùnCorrect E. orúkọExplanation ‘Ti’ jẹ́ atọ́kùn.
“Ìwọ pẹ̀lú Adígún ni ẹ lọ.”
Ọ̀rọ̀ àsopọ̀ ni
A. AdígúnB. ìwọC. lọD. niE. pẹ̀lúCorrect Explanation ‘Pẹ̀lú’ so Ìwọ àti Adígún pọ̀.
Èwo ni kì í ṣe ọ̀rọ̀ orúkọ nínú àwọn wọ̀nyí?
A. ÀṣáB. AwéC. BínúCorrect D. Bọ̀dèE. Kọ́láExplanation ‘Bínú’ jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe.
“Ó wá àmọ́ kò dúró”, ‘àmọ́’ jẹ́ ọ̀rọ̀
A. àpèjúweB. àpọ́nléC. àsopọ̀Correct D. atọ́kùnE. ìṣeExplanation ‘Àmọ́’ so gbólóhùn méjì pọ̀; àsopọ̀ ni.
Ọ̀rọ̀ wo ni ó ń ṣe àfikún ìtumọ̀ fún ọ̀rọ̀ ìṣe nínú gbólóhùn? Ọ̀rọ̀
A. àpèjúweB. àpọ́nléCorrect C. ẹyánD. ìṣeE. orúkọExplanation Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ń ṣàfikún ìtumọ̀ fún ọ̀rọ̀ ìṣe.
“Mo rí Adéwálé ní ìta.” Ìsọrí gírámà ni ‘mo’?
A. AfarajorúkọB. ÀpèjúweC. Àpólà ọ̀rọ̀ orúkọD. Àpọ́nléE. Arọ́pò orúkọCorrect Explanation ‘Mo’ jẹ́ arọ́pò orúkọ ẹnìkínní ẹnìkan.
“Ẹ gbọ́dọ̀ tètè dé” jẹ́ gbólóhùn
A. alálàyéB. alétẹnumọ́C. aṣeD. àṣẹCorrect E. àyísódìExplanation Gbólóhùn tó ń pàṣẹ ni àṣẹ.
“Sùn re o” jẹ́ gbólóhùn
A. abódéB. alákànpọ̀C. àṣẹCorrect D. ayísódìE. olópò ọ̀rọ̀ ìṣeExplanation Ó ń pàṣẹ fún ẹni láti sùn; àṣẹ ni.
Èwo ni kì í ṣe gbólóhùn kíkún?
A. Ìyá Ọlá pa adìyẹ funfun.B. Mo gbàgbé sùn lọ.C. Ó jẹ dòdò.D. Olú bu omijé lójú.E. Tí mo mọ̀Correct Explanation ‘Tí mo mọ̀’ kò ní ìtumọ̀ kíkún.
ÀKỌTỌ́ ÈDÈ YORÙBÁ
Báwo ni a ṣe ń kọ ‘ẹ̀yìn’ ní ìlànà àkọtọ́ òde òní?
A. ẸìyìnB. Ẹ̀yìnCorrect C. Ẹ̀yìn-inD. Ẹ̀yìnìnE. Ẹ̀yyìnExplanation Ìlànà àkọtọ́ òde òní ń kọ ọ́ ní Ẹ̀yìn.
Èwo ni ó bá ìlànà àkọtọ́ mu nínú àwọn wọ̀nyí?
A. ẸnìàB. ẸnìyànCorrect C. Ẹ̀nìyànD. Ẹni yànE. Ẹnìyàn-ànExplanation ‘Ẹnìyàn’ ni àkọtọ́ tó tọ́.
Ṣípẹ̀lì tó tọ̀nà fún ‘pẹ́ripẹ́riyẹ’ ni
A. pàpẹ́yẹB. pẹ́pẹ́yẹC. pẹ́rípẹ́rìyẹCorrect D. pẹyẹE. piẹpẹ́yẹExplanation ‘Pẹ́rípẹ́rìyẹ’ ni ṣípẹ̀lì tó tọ̀nà.
Èwo ni kò bá àkọtọ́ òde òní mu nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí?
A. ÀánúB. AláàánúC. ÀlàáfíàD. LáéláéE. OrunCorrect Explanation ‘Orun’ yẹ kí a kọ ọ́ ‘ọ̀run’.
Tọ́ka sí èyí tí ó bá àkọtọ́ òde òní mu nínú àwọn wọ̀nyìí.
A. NítorìínàB. NítorínàaC. Nítorí náàCorrect D. N ítorí náàE. NítorínáànExplanation ‘Nítorí náà’ ni àkọtọ́ tó tọ́.
AÁYAN ÒGBUFỌ̀
‘Bádé ran into trouble’ túmọ̀ sí Bádé ______ wàhálà.
A. kó sínúCorrect B. lọ sínúC. rìn sínúD. sáré fò sínúE. sáré wọnúExplanation ‘Ran into trouble’ túmọ̀ sí kó sínú wàhálà.
‘Adé bought a white dress’ túmọ̀ sí Adé ra
A. aṣọ dúdúB. aṣọ funfunCorrect C. aṣọ pupaD. bàtà funfunE. fìlà funfunExplanation White = funfun; dress = aṣọ.
‘The children are drinking pap’ túmọ̀ sí
A. àwọn ọmọ náà ń mu ẹ̀kọ.Correct B. àwọn ọmọ náà ti mu ẹ̀kọ náà tán.C. ọmọ náà fẹ́ mu ẹ̀kọ.D. ọmọ náà jẹ ẹ̀kọ yó.E. ọmọ náà lọ ra ẹ̀kọ.Explanation ‘Are drinking’ jẹ́ ìgbà tó ń lọ lọ́wọ́: ń mu.
‘Bùnmi is a smart girl’ túmọ̀ sí Bùnmi jẹ́
A. oníwà pẹ̀lẹ́B. ọmọbìnrin líleC. ọmọbìnrin pupaD. ọmọbìnrin tí ó fẹ́ràn oúnjẹE. ọmọbìnrin tí ó jáfáfáCorrect Explanation Smart = jáfáfá.
‘It is dangerous to play in the rain’ túmọ̀ sí
A. kò dára kí ènìyàn máa rìn nínú òjò.B. kò dára kí òjò máa rọ̀.C. ó dára kí á máa ṣe eré nínú òjò.D. òjò kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó ń ṣe eré.E. ó léwu kí ènìyàn máa ṣe eré nínú òjò.Correct Explanation Dangerous = léwu; play = ṣe eré.
PAPER II
ÌTÀN ÌṢẸ̀DÁLẸ̀ YORÙBÁ
Orúkọ oyè ọba ilú Ẹ̀gbá ni
A. AláàfinB. AlákéCorrect C. Awùjalẹ̀D. OlúbàdànE. ÒṣemàwéExplanation Aláké ni ọba Ẹ̀gbá.
Ìlú tí Odùduwà tẹ̀dó sí ni
A. ÈkóB. Ìjẹ̀búC. Ilé-Ifẹ̀Correct D. Ọ̀yọ́E. Ọ̀wọ̀Explanation Odùduwà tẹ̀dó sí Ilé-Ifẹ̀.
Orúkọ oyè ọba ilú wo ni Èwí?
A. Abẹ́òkútaB. Adó ÈkìtìCorrect C. Èkó ÈkóD. OndóE. ÒṣogboExplanation Èwí ni ọba Adó Èkìtì.
Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọkànbí ni
A. AjeròB. AláráC. OlówuCorrect D. Ọlọ́fàE. Ọlọ́jẹ̀ẹ̀Explanation Olówu wà lára àwọn ọmọ Ọkànbí.
Onípópó jẹ́ ọmọ
A. AlákéB. GògòbíríC. KúkáwíD. ỌkànbíCorrect E. Ọ̀rànmíyànExplanation Onípópó jẹ́ ọmọ Ọkànbí.
BÍ ÈDÈ YORÙBÁ ṢE DI KÍKỌ SÍLẸ̀
Ta ni ó túmọ̀ Bíbélì láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí Yorùbá?
A. Bishop Àjàyí Crowther.Correct B. Herbert Macaulay.C. John Raban.D. Mary Slessor.E. Williams Wilberforce.Explanation Bishop Àjàyí Crowther ni ó túmọ̀ Bíbélì sí Yorùbá.
Àwọn ẹlẹ́sìn wo ló ṣe agbátẹrù bí èdè Yorùbá ṣe di kíkọ sílẹ̀? Ẹlẹ́sìn
A. BúdìB. HíńdùC. Ìbílẹ̀D. Ìgbàgbọ́Correct E. MùsùlùmíExplanation Àwọn Kristẹni ló ṣe agbátẹrù.
Ìwé ìròyìn àkọ́kọ́ ní èdè Yorùbá jáde ní ọdún
A. 1810B. 1844C. 1856D. 1859Correct E. 1862Explanation Ìwé Ìròyìn jáde ní ọdún 1859.
Ọmọ adúláwọ̀ tó kọ́kọ́ wáàsù lédè Yorùbá ni
A. AvezacB. Bishop Ajayi CrowtherCorrect C. GoodnessD. KilhamE. Mary SlessorExplanation Bishop Ajayi Crowther ni.
Ìpinnu tí ó di òfin fún àkọtọ́ èdè Yorùbá tí à ń lò lódé òní wáyé ní ìpàdé ọdún
A. 1844B. 1852C. 1963D. 1966Correct E. 1974Explanation Ìpàdé tó fi àkọtọ́ òde òní lélẹ̀ wáyé ní ọdún 1966.
ÀWỌN Ẹ̀YÀ YORÙBÁ
Ẹ̀ka èdè Yorùbá wo ni ó súnmọ́ Yorùbá àjùmọ̀lò jù?
A. Ẹ̀kìtìB. Ẹ̀gbáC. Ìjẹ̀ṣàD. Ọ̀yọ́Correct E. YàgbàExplanation Ẹ̀ka èdè Ọ̀yọ́ ló súnmọ́ Yorùbá àjùmọ̀lò jù.
Ta ni Ọ̀rànmíyàn fi sí ààfin Ifẹ̀ láti máa tọ́jú ibẹ̀ nígbà tí ó fẹ́ lọ gbẹ̀san ikú bàbá rẹ̀?
A. ÀdìmúlàCorrect B. AlákétuC. OlówuD. ỌbàtáláE. ṢàngóExplanation Àdìmúlà ni a fi sí ààfin Ifẹ̀.
Babańlá àwọn Yorùbá ni
A. AláàfinB. OdùduwàCorrect C. ỌòniD. Ọ̀rànmíyànE. ÒrúnmìlàExplanation Odùduwà ni babańlá àwọn Yorùbá.
Oúnjẹ tí ó gbajúmọ̀ láàrín àwọn Ìjẹ̀bú ni
A. àmàlàB. ẹ̀kọC. fùfúD. ìkókoréCorrect E. iyánExplanation Ìkókoré jẹ́ oúnjẹ Ìjẹ̀bú.
Níbo ni Ṣàngó ti wọ ilẹ̀?
A. FídítìB. Ìjẹ̀búC. Ilé-Ifẹ̀D. IráE. KòsoCorrect Explanation Ṣàngó wọ ilẹ̀ ní Kòso.
LÍTÍRÉṢỌ̀ ALOHÙN/ÀPILẸ̀KỌ ÀTI AJẸMÁYẸYẸ
Ẹ̀yà Yorùbá wo ni ó ní ẹ̀gè?
A. Ẹ̀kìtìCorrect B. Ẹ̀gbáC. ÌgbómìnàD. Ìjẹ̀ṣàE. OndóExplanation Ẹ̀kìtì ni ó ní ẹ̀gè.
Èwo nínú àwọn wọ̀nyí ni ó ní iyẹ̀rè-ifá?
A. BabaláwoCorrect B. EléégúnC. OlóròD. OnísàngóE. Ọlọ́yaExplanation Babaláwo ló ní iyẹ̀rè-ifá.
Orin bíríipo wọ́pọ̀ ní agbègbè
A. Ẹ̀kìtìB. Ìjẹ̀ṣàC. Ìkálẹ̀Correct D. OndóE. Ọ̀yọ́Explanation Orin bíríipo wọ́pọ̀ ní Ìkálẹ̀.
A máa ń ______ ìjálá.
A. dáB. jẹC. kọCorrect D. múE. sunExplanation A máa ń kọ ìjálá.
Ẹ̀yà Yorùbá wo ló ní apẹpẹ?
A. Ẹ̀kìtìB. ẸgbádòC. Ìjẹ̀búCorrect D. Ìjẹ̀ṣàE. OndóExplanation Ìjẹ̀bú ló ní apẹpẹ.
Dadakúàdà jẹ́ ewì ti ilẹ̀
A. Ẹ̀kìtìB. Ẹ̀gbáC. ÌbàràpáD. ÌgbómìnàE. Ọ̀yọ́Correct Explanation Dadakúàdà jẹ́ ewì ilẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ewì ajẹmáyẹyẹ ni ìwọ̀nyí àyàfi
A. alámọ̀Correct B. bọ̀lọ̀jọ̀C. dadakúàdàD. iwìE. orin etíyẹríExplanation Alámọ̀ kì í ṣe ewì ajẹmáyẹyẹ.
Èwo ni a kìí lò níbi gbogbo ayẹyẹ nínú àwọn wọ̀nyí?
A. Ẹ̀gèB. Ẹ̀fẹ̀C. Ẹkún ìyàwóD. Orin etíyẹríE. RáràCorrect Explanation Rárà kì í ṣe ti gbogbo ayẹyẹ.
Ìlú Ọ̀yọ́ ni ______ ti wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.
A. dadakúàdàCorrect B. ẹ̀fẹ̀C. ẹkún ìyàwóD. obitunE. oleleExplanation Dadakúàdà wọ́pọ̀ ní Ọ̀yọ́.
Sísun ni à ń sun rárà, ______ ni ti bọ̀lọ̀jọ̀.
A. kíkọCorrect B. mímúC. pípèD. sísọE. títìExplanation Rárà ni à ń sun, bọ̀lọ̀jọ̀ ni a ń kọ.
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE
Àwọn oníṣẹ́ wo ni à ń kí báyìí? ‘Àrepa ògún o.’
A. AkòpẹB. Alágbẹ̀dẹCorrect C. AláróD. OnídìríE. ỌdẹExplanation ‘Àrepa ògún’ ni ìkíni àwọn alágbẹ̀dẹ.
A kò gbọdọ̀ fi ______ bọ Èṣù.
A. àdíB. ajáC. epoD. emuE. obìCorrect Explanation Obì kò dára fún bíbọ Èṣù.
Òṣìṣẹ́ wo ni à ń kí báyìí? ‘Igbà á rọ̀ o.’
A. ÀgbèCorrect B. AkòpẹC. Alágbẹ̀dẹD. AláróE. OnídìríExplanation ‘Igbà á rọ̀’ ni ìkíni àgbè.
‘Àrẹdú o’ ni à ń kí àwọn
A. alágbẹ̀dẹB. aláróCorrect C. akòpẹD. apẹjaE. onídìríExplanation ‘Àrẹdú’ ni ìkíni aláró.
Ìdílé ______ ni ó ń sọ ọmọ wọn ní Ọjẹ́dìran.
A. babaláwoB. eléégúnC. olóyèD. onílùE. ọdẹCorrect Explanation Ọjẹ́dìran jẹ́ orúkọ ọmọ ìdílé ọdẹ.
Ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ni à ń kí ní ‘Àrọ́yè oo.’
A. AkòpẹB. Alágbẹ̀dẹC. AláróD. ApẹjaE. OnídìríCorrect Explanation ‘Àrọ́yè’ ni ìkíni onídìrí.
Èwo ni kò sí nínú aṣọ àwọn ọkùnrin nínú àwọn wọ̀nyí?
A. DàńdógóB. DàńṣíkíC. GbáríyèD. Ọ̀yàlàE. Yẹ̀rìCorrect Explanation Yẹ̀rì kì í ṣe aṣọ ọkùnrin.
‘Ojúgbooro o’ ni à ń kí
A. àgbèB. gbẹ́nàgbẹ́nàCorrect C. onídìríD. onílùE. ọdẹExplanation ‘Ojúgbooro’ ni ìkíni gbẹ́nàgbẹ́nà.
Ohun èlò akọ̀pẹ nínú àwọn wọ̀nyìí ni
A. aróB. ẹwìrìC. ìbọnD. igbáCorrect E. òwúExplanation Akọ̀pẹ máa ń lo igbá fún ọtí ògùrọ̀.
Ọ̀kan nínú àwọn ìdílé wọ̀nyí ni ó ń jẹ́ Ayándáre.
A. BabaláwoB. Ológùn únC. OnílùCorrect D. OnísàngóE. Ọlọ́yaExplanation Ayándáre jẹ́ orúkọ ìdílé onílù.
ERÉ ONÍṢẸ́ (DRAMA)
Lásúnkànmí Tẹ̀là: ṢUBÚ ṢERÉ
Ìrú ẹ̀bùn wo ni Ọlálékè ní?
A. Àlá líláB. Eré sísáC. Ijó jíjóD. Ìwé kíkàE. Orin kíkọCorrect Explanation Ọlálékè ní ẹ̀bùn orin kíkọ.
Ta ni òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ nínú àwọn wọ̀nyí?
A. AdébaríB. Adùnọ̀láCorrect C. Ẹ̀bùnlọ́mọD. Fadékẹ́E. OlúwọléExplanation Adùnọ̀lá ni òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́.
Ọdún ______ ni Ọlálékè fi ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Ọ̀tan Ayégbajú.
A. kanB. méjìC. mẹ́taCorrect D. mẹ́rinE. mẹ́fàExplanation Ọdún mẹ́ta ni.
Ìgbésẹ̀ wo ni Jùmọ̀kẹ́ gbé láti jogún ọkọ rẹ̀? Ó
A. bẹ àwọn ajínigbé níṣẹ́ sí ọkọ rẹ̀.B. jí ìwé sọ̀wédowó rẹ̀.C. lọ sòògùn tí yóò fi pa á.Correct D. purọ́ mọ́ ọn lọ́dọ̀ ẹbí.E. ta ilé ọkọ rẹ̀ ní ìdákọ́ńkọ́.Explanation Jùmọ̀kẹ́ lọ sòògùn láti pa ọkọ rẹ̀.
Orúkọ ìjọ tí àṣírí Tọ̀nadé àti Olúwọlé ti tú ni
A. Ìfẹ́ Olúwa Bible ChurchB. Ilẹ̀ Àánú Olúwa kìí ṣúC. Orí Òkè ÀánúD. Orí Òkè JádèCorrect E. Ṣómólú Bible ChurchExplanation Orí Òkè Jádè ni orúkọ ìjọ náà.
Eré onísẹ́ (Drama)
D. O. Àdìsá: OLÚ ỌMỌ
Ibo ni àwọn ọmọ tó ń lọ Ìlú Ọba yóò ti lọ ṣe àyẹ̀wò?
A. Ààfin kábíyèsíB. Àgó ọlọ́pàáC. Ilé-ẹ̀kọ́Correct D. Ilé ìfiwéránṣẹ́E. Ilé ìjọ́sìn oníkálukúExplanation Àyẹ̀wò ìdánwò wáyé ní ilé-ẹ̀kọ́.
Òdiwọ̀n tí wọ́n lò fún àwọn tí wọ́n yẹ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún ni kíkìdá
A. àlejò tí ó bá ti lò ju ọdún mẹ́wàá nílùú.B. àwọn obìnrin tó rẹwà, tí wọ́n sì ń mú yangàn lágbo.C. ọmọ ìlú tó bá jẹ́ ọmọkùnrin tí ó lẹ́wà jùlọ.D. ọmọkùnrin tó mọ nípa iṣẹ́ oko àti ohun ọ̀sìn jùlọ.E. ọmọ tó bá yege jùlọ nínú èdè Òyìnbó, ìṣirò àti iṣẹ́ mẹ́ta mìíràn nínú ìdánwò ti wàyéèkì.Correct Explanation Ìdánwò ni wọ́n fi ṣe òdiwọ̀n.
Èwo ni kò sí lára ìlọsíwájú tí ó dé bá ìlú Fèyíkọ́gbọ́n láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ọlọ́dọọdún wọn?
A. Mímú àṣepọ̀ tó gúnmọ́ wà láàrin wọnB. Mímú pàtàkì ẹ̀kọ́ lọ́kùn-ún-kúndùnC. Oore ọ̀fẹ́ láti fẹ̀ àjèjìD. Oúnjẹ pípín ojoojúmọ́Correct E. Wíwọ aṣọ tí ó bá ìgbà muExplanation Pípín oúnjẹ ojoojúmọ́ kò sí lára wọn.
Inú oṣù wo ni ayẹyẹ ọlọ́dọọdún ti ìlú Fèyíkọ́gbọ́n máa ń wáyé? Oṣù
A. ẹrèléB. ògúnCorrect C. ọ̀pẹD. ọ̀wàràE. ṣẹrẹExplanation Ayẹyẹ náà wáyé ní oṣù Ògún.
Àbá kí á fi oyè dá àwọn ọmọ ìlú lọ́lá fún ipa pàtàkì tí wọ́n ń kó nílùú wá láti ọ̀dọ̀
A. ÀgùròB. ÌyálódeC. JagunD. KábíyèsíCorrect E. Olóyè ọ̀túnExplanation Kábíyèsí ni olórí ìlú tó ń fi oyè dá ni lọ́lá.
Ìtàn Àròsọ (Prose)
Diípò Gbénró: ATÍTẸ̀ẸBÍ
Ìyá Olú kúrò nílé ọkọ nítorí
A. àrùn ọpọlọ tí ó kọlù ú.B. ìnàkunà tí ọkọ rẹ̀ ń nà án.C. ìyá ọkọ rẹ̀ tí ó gbógun tì í.D. ìyàwó kejì tí ọkọ rẹ̀ fẹ́ wọlé.Correct E. ọkọ rẹ̀ fún un ní ìwé ìkòsílẹ̀.Explanation Ìyá Olú kúrò nítorí ìyàwó kejì tí ọkọ rẹ̀ fẹ́.
Níbo ni wọ́n ti ṣe pàtí ọjọ́ ìbí Olúṣeyi?
A. Gbọ̀ngàn ìlúB. Ilé ìturaC. Ìta ilé bàbá rẹ̀Correct D. Orí pápá ìṣeréE. Pálọ̀ bàbá rẹ̀Explanation Wọ́n ṣe é ní ìta ilé bàbá rẹ̀.
Àwọn wo ni wọ́n wà ní pàtí Atítẹ̀ẹ̀bí ní ojú ọ̀sán? Àwọn
A. akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀B. ọmọ alábàáágbé wọnC. ọ̀rẹ́ ìyá àti bàbá rẹ̀Correct D. ọ̀rẹ́ rẹ̀ obìnrinE. tí wọ́n jọ ń mugbóExplanation Àwọn ọ̀rẹ́ ìyá àti bàbá rẹ̀ ni.
Tọ́ka sí oúnjẹ tí wọn kò sè níbi ayẹyẹ ìkómọjáde Olúṣèyí nínú ìwọ̀nyí.
A. ÀmàlàCorrect B. Ìkọ́kẹ́réC. ÌrẹsìD. IyánE. Mọ́ímọ́ínExplanation Àmàlà kò sí lára oúnjẹ tí wọ́n sè.
Èló ni owó sáà ilé-ẹ̀kọ́ tí Olúṣèyí ti bẹ̀rẹ̀? Ẹgbẹ̀rún ______ náírà
A. méjeB. mẹ́jọC. mẹ́wàáCorrect D. mọ́kànláE. méjìláExplanation Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà.
Ọláẹ̀jùmọ̀kẹ́ Bámitékòó: SISÍ ỌLỌ́JÀ
Fúnkẹ́ ṣẹ̀wọ́n ní orílẹ̀ èdè
A. GambiaB. LibyaCorrect C. MoroccoD. RabatE. SpainExplanation Fúnkẹ́ ṣẹ̀wọ́n ní Libya.
Fúnkẹ́ wà ní ______ nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ ń wá a.
A. agbo fààjìB. ilé ìwòsànC. ilé oúnjẹD. inú ọjà dùgbẹ̀E. pátí ọjọ́ ìbí StellaCorrect Explanation Fúnkẹ́ wà ní pátí ọjọ́ ìbí Stella.
Orúkọ ọ̀rẹ́bìnrin Fúnkẹ́ tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ ṣe alábàápàdé Bámijí ni
A. Adélàńkẹ́B. Bùkọ́láC. DáràD. DèbóràE. StellaCorrect Explanation Stella ni ọ̀rẹ́bìnrin náà.
Lẹ́yìn tí Adélàńkẹ́ jáde ìwé mẹ́wàá, ó kọ́ iṣẹ́
A. aṣọ híhunB. aṣọ ríránCorrect C. fọ́tò yíyàD. obì sísinE. oúnjẹ títàExplanation Ó kọ́ aṣọ rírán.
Níbo ni Fúnkẹ́ tọ́jú òògùn olóró tí ó gbé lọ Libya sí? Inú
A. búrẹ́dìB. ẹwàC. ìrẹsìD. kéèkìCorrect E. ògìExplanation Ó fi sí inú kéèkì.
Ewì (Poetry)
Kọ́lá Ajíbóyè: ÌJÌNLẸ̀ ÀRỌ́FỌ̀ MẸ́Ẹ̀DÓGBỌ̀N
Ta ni ó ń gun igi lọ fọn fèrè nínú ewì ‘Àjàmúpo’?
A. Àbúrò ÀjàmúpoB. ÀjàmúpoCorrect C. Bàbá ÀjàmúpoD. Ẹgbọ́n ÀjàmúpoE. Ìyá ÀjàmúpoExplanation Àjàmúpo ni ó ń gun igi fọn fèrè.
Nínú ewì ‘Akàrà Ojúde Ẹni,’ akàrà ojúde ẹni kì í ní iyọ̀ ṣùgbọ́n bí a bá rà á
A. iyọ̀ díẹ̀ ni a ó fi sí i.B. kìí jẹ́ kí ebi ó pa ni.Correct C. ó dára ju ti ibòmíràn lọ.D. ó ṣara ní oore.E. wọn yóò fi èèni díẹ̀ sí.Explanation Akàrà ojúde ẹni kìí jẹ́ kí ebi pa ni.
Kín ni kò jẹ́ kí Àjàmúpo joyè ilé bàbá rẹ̀ nínú ewì ‘Àjàmúpo’?
A. Agídí ọkànB. Ìjọ̀ngbọ̀n rẹ̀ tí ó pòC. Kò fẹ́ẹ̀ kúCorrect D. Ọgbọ́n àgbọ́nforoE. Ọ̀rọ̀ àsọtánExplanation Bàbá rẹ̀ kò fẹ́ẹ̀ kú.
Kókó ohun tí ewì ‘Akàrà Ojúde Ẹni’ dá lé lórí ni kí á
A. gbé ohun tí a ní lárugeCorrect B. ní sùúrùC. máa hùwà rereD. tẹpá mọ́ṣẹ́E. ya akíkanjú ẹ̀dáExplanation Ewì náà ń gbé ohun tí a ní láruge.
Tẹni-n-tẹni, ti ______ ni tààtàn bí a ṣe rí i kà nínú ewì ‘Akàrà Ojúde Ẹni’.
A. àkísàB. ẹ̀gbinC. ìdọ̀tíD. ìgbẹ́E. ìtọ̀Correct Explanation Ewì náà sọ ti ìtọ̀.
Sign up free to unlock Score tracking Practice history Saved questions Progress dashboard Personalized sessions Weak-topic breakdown…and/or go further with premium services and No Ads .