BECE Yoruba Language 2023 Objective — Question 6
Question 6 of 120 from the Basic Education Certificate Examination (Junior WAEC) (BECE) Yoruba Language 2023 Objective paper, with the correct answer and a full explanation.
Advertisement
SECTION 2 (ÌPÍN KEJÌ) ÀKÀYÉ KEJÌ Afọlábí: Mo mà gbádùn ọbẹ̀ elégédé tí mo fi jẹ iyán ọ̀sán yìí gan an o. Àkànkẹ́: Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pa á, baálé mi. Afọlábí: Bẹ́ẹ̀ ni tìrẹ rí, aya rere lóòdẹ̀ ọkọ. Àkànkẹ́: Mo rí ìwé ọmọ yín ní ọ̀sán yìí, ó ní kí n kí i yín. Afọlábí: Ṣé àlàáfíà ni ó wà? Nítòótọ́ obìnrin ni Ẹ̀sítà, ṣùgbọ́n ṣáṣà ọmọkùnrin ló lè ṣe ohun tó ń ṣe yìí, lẹ́nu ọ̀sẹ̀ mẹ́rin tí ó padà sí ilé-ẹ̀kọ́, lẹ́tà rẹ̀ ti di méjì. Àkànkẹ́: Ọmọbìnrin dára lóòótọ́ ṣùgbọ́n ọmọkùnrin ló dára jù. Ọmọbìnrin le ṣe aájò nígbà tó bá wà ní wúndíá, tó bá ti délé ọkọ tán, “akẹ̀yìnsí abiyamọ kò gbẹ́kùn ní ọ̀rọ̀ wọn.” Afọlábí: Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọkùnrin ni ọ̀nà wọn pọ̀; tí wọ́n kìí rójú gbọ́ ti àwọn òbí wọn ṣùgbọ́n kò sì bí ojú ṣe lè dí tó, tí ọmọbìnrin kò ní ránti òbí rẹ̀. Àkànkẹ́: Ṣebí obìnrin ni èmi náà, òní ti ìyá ọkọ, ọ̀la ti bàbá ọkọ, ọ̀tunla ti orogún ilé, kìí jẹ́ kí ọmọbìnrin rí ààyè mójútó òbí rẹ̀. Èyí ni mo fi sọ pé, ọmọkùnrin wúlò fún òbí ju ọmọbìnrin lọ. Afọlábí: Gbogbo ohun tí ọkùnrin lè ṣe náà ni obìnrin lè ṣe, kí Ọlọ́run fún wa ní aláàánú ọmọ ni kókó àdúrà. Àkànkẹ́: Àṣẹ! àmọ́ ọmọkùnrin ni èmi ń fẹ́, kí Ọlọ́run fún mi lọ́mọkùnrin pẹ̀lú Ẹ̀sítà, kí wọ́n lè di méjì sími lọ́wọ́. Afọlábí: Àmín, ká ẹni wọlé kúrò lábẹ́ igi ọdán ká lọ sùn. Àdúrà rẹ ti gbà. Àkókò wo ni ìtàkurọ̀sọ yìí wáyé?
- A. Alẹ́
- B. Ìyálẹ̀ta
- C. Òwúrọ̀ kùtù
- D. Ọgànjọ́ òru
- E. Ọ̀sánCorrect
Explanation
Afọlábí sọ pé wọ́n jẹ iyán ní ọ̀sán yìí.
Advertisement
Sign up free to unlock
- Score tracking
- Practice history
- Saved questions
- Progress dashboard
- Personalized sessions
- Weak-topic breakdown
…and/or go further with premium services and No Ads.