Free account: track your progress — Sign up free

JSCE Yoruba Language 2023 Objective — Question 1

Question 1 of 100 from the Junior Secondary Certificate Examination (JSCE) Yoruba Language 2023 Objective paper, with the correct answer and a full explanation.

Advertisement

ÀKÍYÈSÍ:- Ka àkàyé ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì dáhùn gbogbo Ìbéèrè tó wà lábẹ́ rẹ̀. A ṣe bótọ́ ni ọ̀rọ̀ àgbà tó wí pé "ẹni tí ó bá ṣiṣẹ́ ọmọ ni yóò jèrè ọmọ". Adérónkẹ́ jẹ́ Olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga onípele kínní. Ó sì bí ọmọbìnrin mẹ́ta fún Adìsá Ọkọ rẹ̀. Adìsá gbàgbọ́ pé ọmọbìnrin kò lè mú èrè kankan wá fún òun. Ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí baba fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ obìnrin, Adérónkẹ́ gba kámú ó sì fún ọjà rẹ̀ le. Ó gbà wí pé òun ti bí àwọn ọmọbìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí fún ara òun. Oyèpéjú jẹ́ àkọ́bí, Ọláníkẹ́ẹ̀ ni ó tẹ̀lé e nígbà tí Gbọ́njúbọ́lá jẹ́ àbígbẹ̀yìn. Adérónkẹ́ sa gbogbo agbára rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ tí ó yẹ kooro. Nígbà tí Oyèpéjú kẹ́kọ̀ọ́ gboyè tán ní Yunifásítì, ó rí iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ńlá tí wọ́n ti ń wa epo ròbì. Lẹ́yìn ọdún méjì ni ó tún rí iṣẹ́ mìíràn sí ìlú Ọba. Èyí mú kí Oyèpéjú kó àwọn àbúrò rẹ̀ méjèèjì lọ sí òkè òkun láti lọ parí ẹ̀kọ́ Yunifásítì wọn ní Òkè Òkun. Gbogbo àwọn ọmọbìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí padà di Olóríire àti Ọlọ́lá ènìyàn láwùjọ. Wọ́n ṣe ìtọ́jú Mámá wọn dáadáa láti fi ẹ̀mí ìmọ̀ríì hàn án. Adìsá baba wọn náà sì kábàámọ̀ ìwà àìnáání àwọn ọmọ Olóríire tí Ọlọ́run fún un, nítorí pé wọ́n jẹ́ Obìnrin. Ó kọ́gbọ́n pé kò sí nǹkan tí Ọkùnrin ń ṣe tí Obìnrin kò lè ṣe. Ta ni Olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga onípele Kìnní?

  • A. Adérónkẹ́Correct
  • B. Ọláníkẹ́ẹ̀
  • C. Gbọ́njúbọ́lá
  • D. Oyèpéjú

Explanation

Adérónkẹ́ ni olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga onípele kìnní.

Advertisement

Sign up free to unlock

  • Score tracking
  • Practice history
  • Saved questions
  • Progress dashboard
  • Personalized sessions
  • Weak-topic breakdown

…and/or go further with premium services and No Ads.