Free account: track your progress — Sign up free

JSCE Yoruba Language 2023 Objective Past Questions

All 100 questions from the Junior Secondary Certificate Examination (JSCE) Yoruba Language 2023 Objective paper, with the correct answer and a full explanation for each. Free, no signup needed.

Advertisement

Yoruba Language 2023 Objective — Question 1

ÀKÍYÈSÍ:- Ka àkàyé ìsàlẹ̀ yìí, kí o sì dáhùn gbogbo Ìbéèrè tó wà lábẹ́ rẹ̀. A ṣe bótọ́ ni ọ̀rọ̀ àgbà tó wí pé "ẹni tí ó bá ṣiṣẹ́ ọmọ ni yóò jèrè ọmọ". Adérónkẹ́ jẹ́ Olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga onípele kínní. Ó sì bí ọmọbìnrin mẹ́ta fún Adìsá Ọkọ rẹ̀. Adìsá gbàgbọ́ pé ọmọbìnrin kò lè mú èrè kankan wá fún òun. Ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí baba fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ obìnrin, Adérónkẹ́ gba kámú ó sì fún ọjà rẹ̀ le. Ó gbà wí pé òun ti bí àwọn ọmọbìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí fún ara òun. Oyèpéjú jẹ́ àkọ́bí, Ọláníkẹ́ẹ̀ ni ó tẹ̀lé e nígbà tí Gbọ́njúbọ́lá jẹ́ àbígbẹ̀yìn. Adérónkẹ́ sa gbogbo agbára rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ tí ó yẹ kooro. Nígbà tí Oyèpéjú kẹ́kọ̀ọ́ gboyè tán ní Yunifásítì, ó rí iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ńlá tí wọ́n ti ń wa epo ròbì. Lẹ́yìn ọdún méjì ni ó tún rí iṣẹ́ mìíràn sí ìlú Ọba. Èyí mú kí Oyèpéjú kó àwọn àbúrò rẹ̀ méjèèjì lọ sí òkè òkun láti lọ parí ẹ̀kọ́ Yunifásítì wọn ní Òkè Òkun. Gbogbo àwọn ọmọbìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí padà di Olóríire àti Ọlọ́lá ènìyàn láwùjọ. Wọ́n ṣe ìtọ́jú Mámá wọn dáadáa láti fi ẹ̀mí ìmọ̀ríì hàn án. Adìsá baba wọn náà sì kábàámọ̀ ìwà àìnáání àwọn ọmọ Olóríire tí Ọlọ́run fún un, nítorí pé wọ́n jẹ́ Obìnrin. Ó kọ́gbọ́n pé kò sí nǹkan tí Ọkùnrin ń ṣe tí Obìnrin kò lè ṣe. Ta ni Olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga onípele Kìnní?

  • A. Adérónkẹ́Correct
  • B. Ọláníkẹ́ẹ̀
  • C. Gbọ́njúbọ́lá
  • D. Oyèpéjú

Explanation

Adérónkẹ́ ni olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga onípele kìnní.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 4

Epo ròbì jẹ́..........

  • A. Ohun tí a tí máa ń rí omi mímu
  • B. Ohun tí ó ń fún wa ní iyọ̀
  • C. Ohun tí ó máa ń fún wa ní epo pupa
  • D. Ohun tí ó máa ń fún wa ní epo pẹ̀tírólùCorrect

Explanation

Epo ròbì (epo rọ̀bì) ni orísun epo pẹ̀tírólù.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 5

Àkọlé wo ni ó bá àyọkà yìí mu?

  • A. Ọmọbìnrin dára ju Ọmọkùnrin lọCorrect
  • B. Bàbá kò fẹ́ràn ọmọ
  • C. Ọmọbìnrin mẹ́ta
  • D. Gbogbo ọmọ

Explanation

Àyọkà náà fi hàn pé ọmọbìnrin dára bí ọmọkùnrin; àkọlé tó bá a mu ni èyí tó sọ pé ọmọbìnrin dára ju ọmọkùnrin lọ.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 6

ÀKÀYÉ EWÌ: Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, Ìyá mi máa ń fú mi ní wàrà, Bàbá mi a sì máa fi ṣíbí fún mi lóúnjẹ. N kò mọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀, Tí wọ́n fi ń ṣe ìtọ́jú yìí fún mi, Ṣùgbọ́n nígbà tí mo dàgbà, Ìyá mi ń retí kí n wá Ṣanjó, Bàbá mi fẹ́ kí n fi ṣíbí tọ́mi sóun lẹ́nu. Ìgbà náà ló tó yé mi Kedere pé, Bíbọ́ tí wọ́n ń bọ́ mi nígbà èwe, Nítorí ọjọ́ ogbó wọn ni. Nítorí bókété bá dàgbà tán, Ọmú ọmọ rẹ̀ ni yóò máa mu. Nítorí ká lè rẹ́ni ké sí, La fi ń tọ́jú ọmọ. Nítorí ká lè rẹ́ni fẹ̀yìntì, La fi ń mójú tọ́mọ. Kò ṣẹ́ni tó mọ ìdí òjò, Bí ò ṣe Ṣàngó. Kò ṣẹ́ni tó mọ ohun tómele ń wí, Tó ju ẹni tó gbómele lọ́wọ́ lọ. Kò ṣẹ́ni tó mójú ọwá, Tó ju ẹyin lójú ọwá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni kò ṣẹ́ni tó lè mọ̀ ọ́n-pọ̀n, Tó yàtọ̀ sí ọlọ́mọ. Edùmàrè jẹ́ a rọ́mọ tọ́jú ẹni, Nítorí ọmọ ní í róni tó ju aṣọ lọ. Ṣanjó tí akéwì mẹ́nu bà nínú ewì yìí túmọ̀ sí ..............

  • A. Owó
  • B. Oúnjẹ
  • C. Ìtọ́júCorrect
  • D. Oko

Explanation

Ìyá ń retí kí ọmọ wá ṣe ìtọ́jú òun; ìtumọ̀ ni ìtọ́jú.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 7

Ọ̀rọ̀ míìràn fún kedere ní ìlà Kẹsàn-án ewì yìí ni.

  • A. Ìmọ́lẹ̀
  • B. GbangbaCorrect
  • C. Kólọ́fín
  • D. Òkùnkùn

Explanation

Kedere túmọ̀ sí gbangba (ṣe kedere = ṣe gbangba).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 10

Akọlé tí ó bá ewì yìí mu ni..........

  • A. Ìgbà ọdó
  • B. Nítorí ọjọ́ ogbóCorrect
  • C. Ìgbà ọ̀sán
  • D. Ìgbà ewe

Explanation

Ewì sọ pé a ń tọ́jú ọmọ nítorí ọjọ́ ogbó.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 11

Ewo ni kò wúlò nínú àròkọ kíkọ lédè Yorùbá.

  • A. Ìlapa èrò
  • B. Ìfáàrà
  • C. Ìgúnlẹ̀
  • D. Àwòrán yíyàCorrect

Explanation

Ìlapa èrò, ìfáàrà àti ìgúnlẹ̀ wúlò nínú àròkọ; àwòrán yíyà kò wúlò.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 12

Irú orí-ọ̀rọ̀ àròkọ wo ni "Owó lẹ́gbọ́n, Ọmọ làbúrò"

  • A. Àròkọ Alálàyé
  • B. Àròkọ AlárìíyànjiyànCorrect
  • C. Àròkọ Aṣọ̀tàn
  • D. Àròkọ Aṣebéèrè

Explanation

Orí-ọ̀rọ̀ tí ó ní ìdojúkọ ni a fi ń kọ àròkọ alárìíyànjiyàn.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 13

Gbogbo èyí ni àǹfààní àròkọ kíkọ, àyàfi ......

  • A. Ìronújinlẹ̀
  • B. Ìmọ èdè lílò
  • C. Ìsọwọ́kọ̀wé tó dára
  • D. Ìlò ohùn ẹnu tó péyeCorrect

Explanation

Àròkọ kíkọ kò kọ́ni ní ìlò ohùn ẹnu.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 14

Lẹ́tà tí a máa ń kọ sí ọ̀rẹ́ wa ni .....

  • A. Lẹ́tà ìmọ̀ríì
  • B. Lẹ́tà àìgbẹ̀fẹ́Correct
  • C. Lẹ́tà gbẹ̀fẹ́
  • D. Lẹ́tà gbẹ̀fẹ́ àti àìgbẹ̀fẹ́

Explanation

Lẹ́tà sí ọ̀rẹ́ jẹ́ lẹ́tà àìgbẹ̀fẹ́ (aláìgbàgbà).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 15

Lẹ́tà àìgbẹ̀fẹ́ jẹ́ ..........

  • A. Lẹ́tà ìpè
  • B. Lẹ́tà ìfẹ́
  • C. Lẹ́tà mọ̀lẹ́bíCorrect
  • D. Lẹ́tà iṣẹ́

Explanation

Lẹ́tà sí mọ̀lẹ́bí jẹ́ lẹ́tà àìgbẹ̀fẹ́.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 16

Àròkọ lórí iṣẹ́ Àgbẹ̀ jẹ́..........

  • A. Àròkọ AlálàyéCorrect
  • B. Àròkọ Ajẹmọ́sípayá
  • C. Àròkọ Aṣọ̀tàn
  • D. Àròkọ Aṣàpèjúwe

Explanation

Àròkọ tí ń ṣàlàyé iṣẹ́ àgbẹ̀ jẹ́ alálàyé.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 17

Ẹya ara afipè tí a lè fojú rí ni ..........

  • A. Ẹ̀rìgìCorrect
  • B. Inú gògòngò
  • C. Káà ọfun
  • D. Ẹ̀dọ̀ fóró

Explanation

Ẹ̀rìgì ni a lè fojú rí nínú àwọn ẹya ara tí a mẹ́nu bà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 18

Kọ́ńsónáǹtì mélòó ni o wà nínú èdè Yorùbá?

  • A. Ogún
  • B. Mọ́kàndínlógún
  • C. Méjìlélógún
  • D. MéjìdínlógúnCorrect

Explanation

Kọ́ńsónáǹtì èdè Yorùbá jẹ́ méjìdínlógún (18).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 19

Ẹya ara ifọ̀ tí kìí kúrò ní àyè rẹ̀ ni ..........

  • A. Ètè òkèCorrect
  • B. Ètè ìsàlẹ̀
  • C. Ahọ́n
  • D. Iwájú ahọ́n

Explanation

Ètè òkè kì í ṣí nídìí; ìsàlẹ̀ ètè ni ó ń rìn.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 22

Ewo ni kì í ṣe àpólà nínú àwọn wọ̀nyí?

  • A. Àpólà orúkọ
  • B. Ọ̀rọ̀ àpèjúweCorrect
  • C. Àpólà Iṣẹ́
  • D. Àpólà àpọ́nlé

Explanation

Ọ̀rọ̀ àpèjúwe jẹ́ ẹ̀yà ọ̀rọ̀, kì í ṣe àpólà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 23

Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí o máa ń tọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ inú gbólóhùn ni ..........

  • A. Ọ̀rọ̀ – Orúkọ
  • B. Ọ̀rọ̀ – Iṣẹ́Correct
  • C. Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé
  • D. Ọ̀rọ̀ àpèjúwe

Explanation

Ọ̀rọ̀-iṣẹ́ ni ó ń tọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 24

Ṣọlá àti Jídé ni ó wà "àti" nínú gbólóhùn yìí jẹ́ ..........

  • A. Ọ̀rọ̀ àpèjúwe
  • B. Ọ̀rọ̀ Iṣẹ́
  • C. Ọ̀rọ̀ atọ́kùn
  • D. Ọ̀rọ̀ àsopọ̀Correct

Explanation

"Àti" so Ṣọlá àti Jídé pọ̀: ọ̀rọ̀ àsopọ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 25

Ní gbà wo ni o dé? Jẹ́ àpẹẹrẹ....

  • A. Gbólóhùn ìbéèrèCorrect
  • B. Gbólóhùn aṣẹ
  • C. Gbólóhùn ayísódì
  • D. Gbólóhùn ọlọ́pọ̀ ọ̀rọ̀-iṣẹ́

Explanation

Ìbéèrè ni "Ní ìgbà wo ni o dé?": gbólóhùn ìbéèrè.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 26

Apákan gbólóhùn ọlọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ tí ó dá ìtumọ̀ gbólóhùn ní .......

  • A. Àpólà atọ́kùn
  • B. Àpólà àpọ́nlé
  • C. Olórí awẹ́-gbólóhùnCorrect
  • D. Awẹ́ – gbólóhùn afarahẹ

Explanation

Olórí awẹ́-gbólóhùn ló dá ìtumọ̀ dúró fúnra rẹ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 27

Iṣu méje ni mo rà. "Méje" jẹ́

  • A. Ẹ̀yán Ajórúkọ
  • B. Ẹ̀yán AṣòǹkàCorrect
  • C. Ẹ̀yán Aṣàpèjúwe
  • D. Ẹ̀yán Aṣàfihàn

Explanation

Méje ni nọ́mbà, nítorí náà ẹ̀yán aṣòǹkà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 28

Make hay while the sun is shining.

  • A. Ṣe hay Nígbà tí òrùn ń ràn
  • B. Ṣiṣẹ́ ní àkókò iṣẹ́Correct
  • C. Sá aṣọ sínú òrùn
  • D. Pariwo nígbà tí òrùn ń ràn

Explanation

Ìtumọ̀ òwe náà: ṣiṣẹ́ nígbà tí àkókò bá yẹ.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 29

Charity begins at home.

  • A. Fífi ẹ̀bùn fún ni ilé ni ó ti máa ń bẹ̀rẹ̀
  • B. Ọwọ́ fífún ènìyàn bẹ̀rẹ̀ láti iléCorrect
  • C. Ó dára kí a máa fún ènìyàn ní nǹkan
  • D. Ilé lati ń kó ẹ̀ṣọ́ ròde

Explanation

Ọwọ́ fífún ènìyàn bẹ̀rẹ̀ láti ilé.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 30

Ọ̀nà méjì tí a pín Fáwẹ́lì sí ni......

  • A. Àránmúpè àti ayanupè
  • B. Àránmúpè àti afahánpè
  • C. Àránmúpè àti àranjúpè
  • D. Àìránmúpè àti àránmúpèCorrect

Explanation

Fáwẹ́lì pín sí àìránmúpè (ẹnu) àti àránmúpè (imú).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 33

Àwọn ẹya ara ifọ̀ tó dúró gbári sí ojú kan bí a bá ń pe ìró èdè ni ..........

  • A. Afipe asúnsí
  • B. Afáṣẹ
  • C. Ẹ̀dọ̀-fóró
  • D. Afipè akànmọ́lẹ̀Correct

Explanation

Afipè akànmọ́lẹ̀ ni àwọn tí kì í yí ipò padà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 34

Ọ̀rọ̀ tí ó lè ṣiṣẹ́ Olùwà, àbọ̀ tàbí ẹ̀yán nínú gbólóhùn ni ọ̀rọ̀..........

  • A. OrúkọCorrect
  • B. Iṣẹ́
  • C. Àpèjúwe
  • D. Atọ́kùn

Explanation

Ọ̀rọ̀-orúkọ ló lè jẹ́ olùwà, àbọ̀ tàbí ẹ̀yán.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 35

'Kẹ́hìndé ra iṣu tà lójà owódé' Gbólóhùn yìí jẹ́ gbólóhùn..........?

  • A. abọ̀dé
  • B. káni
  • C. ìbéèrè
  • D. ọlọ́pọ̀ ọ̀rọ̀-iṣẹ́Correct

Explanation

Ra àti tà: ọ̀rọ̀-iṣẹ́ méjì wà nínú rẹ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 36

Ewo ni awẹ́ gbólóhùn afarahẹ nínú gbólóhùn yìí? " Mà á wá tí ó bá yá"

  • A. Tí ó bá yáCorrect
  • B. Bá yá
  • C. Màá wá
  • D. Wá tí ó bá yá

Explanation

"Tí ó bá yá" ni awẹ́ afarahẹ; "Màá wá" ni olórí awẹ́.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 37

Ewo ni àpólà orúkọ nínú gbólóhùn yìí? "Bàbá ọdẹ pa ẹyẹ"

  • A. Pa ẹyẹ
  • B. Bàbá ọdẹCorrect
  • C. Ọdẹ pa ẹyẹ
  • D. Ṣe ẹyẹ jẹ

Explanation

Bàbá ọdẹ ni àpólà orúkọ (olùwà).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 38

Àpẹtúnpe Ọ̀rọ̀-Orúkọ ni a fi ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ orúkọ yìí?

  • A. Ìjẹkúje
  • B. Panápaná
  • C. Alaalẹ̀
  • D. Gbọ́mọgbọ́mọCorrect

Explanation

Gbọ́mọgbọ́mọ ni a ṣẹ̀dá nípasẹ̀ àpètúnpè.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 40

Ewo ni ó jẹ́ ọ̀rọ̀ àyálò àfetíyá?

  • A. Bíbélì
  • B. TáàbìlìCorrect
  • C. Tébù
  • D. Mílíìkì

Explanation

Àfetíyá: a yá ọ̀rọ̀ náà nípa gbígbọ́ bí a ṣe ń pè é.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 41

Ewo ni kìí ṣe ara ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ gbólóhùn èdè Yorùbá?

  • A. Ọ̀rọ̀-iṣẹ́
  • B. Ọ̀rọ̀-atọ́kùn
  • C. SílébùCorrect
  • D. Ọ̀rọ̀-orúkọ

Explanation

Sílébù jẹ́ ẹyọ ìró, kì í ṣe ìsọ̀rí ọ̀rọ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 42

Inú .............. ni a ti ń rí kókó gbólóhùn.

  • A. Ọ̀rọ̀ atọ́kùn
  • B. Ọ̀rọ̀ - orúkọ
  • C. Ọ̀rọ̀ – arọ́pò-orúkọ
  • D. Ọ̀rọ̀ – iṣẹ́Correct

Explanation

Kókó gbólóhùn ni ọ̀rọ̀-iṣẹ́.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 43

Ní ìbámu pẹ̀lú àkọtọ́ òde òní, ọ̀rọ̀ mélòó ni ó wà nínú Bíótilẹ̀jẹ́pé.

  • A. Ọ̀rọ̀ méjì
  • B. Ọ̀rọ̀ mẹ́ta
  • C. Ọ̀rọ̀ mẹ́rin
  • D. Ọ̀rọ̀ márùn –únCorrect

Explanation

Bí ó ti lè jẹ́ pé: ọ̀rọ̀ márùn-ún.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 44

Ṣe atúnkọ ọ̀rọ̀ yìí ní àkọtọ́ òde-òní "Ẹbúttẹ-Mẹ́ttà"

  • A. Ẹbúttẹ́ –Mẹ́ttà
  • B. Ẹ̀búté –Mẹ́ttà
  • C. Ẹbúttẹ́ –mẹ́ta
  • D. Ẹ̀búté –mẹ́taCorrect

Explanation

Àkọtọ́ òde-òní kò lo "tt" ṣùgbọ́n "t" kan; Ẹ̀búté-mẹ́ta ni èyí tó sún mọ́ ọn jù.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 45

Ọ̀rọ̀ mélòó ni ó wà nínú "nígbànáà"

  • A. Ọ̀rọ̀ mẹ́ta
  • B. Ọ̀rọ̀ méjìCorrect
  • C. Ọ̀rọ̀ mẹ́rin
  • D. Ọ̀rọ̀ márùn-ún

Explanation

Nígbà náà: ọ̀rọ̀ méjì.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 46

Báwo ni a ṣe ń kọ "Peter" tí a yá wọ inú èdè Yorùbá ní ọ̀nà afojúyá?

  • A. PétérùCorrect
  • B. Pétèr
  • C. Pétèrs
  • D. Pítèr

Explanation

Afojúyá: a yá ọ̀rọ̀ náà láti inú bí a ṣe kọ ọ́; Pétérù ni a fi ń kọ ọ́ nínú Bíbélì Yorùbá.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 47

Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló ṣiṣẹ́ lórí àkọtọ́ èdè Yorùbá àyàfi.

  • A. Alùfáà Ransome KútiCorrect
  • B. Bíṣọ̀ọ̀bù Ajàyí Crowther
  • C. Alùfáà Raban
  • D. Alùfáà Gollmer

Explanation

Gbogbo wọn ni wọ́n kópa; èyí tí a yàn sún mọ́ èyí tí kò tíì kópa pàtàkì.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 50

Tún ọ̀rọ̀ yìí kọ " bíótilèjépé"

  • A. Bí ó tile jé pe
  • B. Bio tile jepe
  • C. Bí ó ti lè jẹ́ péCorrect
  • D. Bí ó tilẹ̀jẹ́ pé

Explanation

Bí ó ti lè jẹ́ pé: ọ̀rọ̀ márùn-ún ni a kọ lọ́tọ̀lọ́tọ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 53

Sọ ọ̀nkà èdè Yorùbá fún 360

  • A. Okòólélọ́ọ̀dúnrún
  • B. Ọ̀tàlélọ́ọ̀dúnrúnCorrect
  • C. Ọ̀rìnlélọ́ọ̀dúnrún
  • D. Ọ̀jìlélọ́ọ̀dúnrún

Explanation

360 = 300 + 60: ọ̀tàlélọ́ọ̀dúnrún (ọgọ́ta + ọ̀ọ́dúnrún).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 54

Ìtumọ̀ ọgọ́jọ́ ni ..........

  • A. Ogó méjọ
  • B. Ẹyí lọ́nà méjọ
  • C. Méjọ lọ́nà méjì
  • D. Ogún méjọCorrect

Explanation

Ọgọ́jọ́ = 160 = ogún méjọ (20 x 8).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 58

Orìṣà tí àwọn Yorùbá máa ń kì ní onílé orita ni ..........

  • A. ÈṣùCorrect
  • B. Ògún
  • C. Ṣàngó
  • D. Ọbàtálá

Explanation

Èṣù ni onílé orita (olùdààbò oríta).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 60

Ewo ni ó jẹ́ ìtọ́jú alábòyún ní ọ̀nà abínibí?

  • A. Oyún dídèCorrect
  • B. Lílọ sí ilé-ìwòṣàn òyìnbó
  • C. Ṣíṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ní ọ̀nà ìgbàlódé
  • D. Lílo àwọn ògùn oníkóró

Explanation

Oyún dídè jẹ́ ìtọ́jú abínibí (ìbílẹ̀).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 61

Ọ̀nà tí a lè gbà dènà ogun jíjà ni ..........

  • A. Gbígbé sùmọ̀mí
  • B. Gbígba ìyàwó oníyàwó
  • C. Mímú idà nínú àrokò ogun tí wọ́n pa
  • D. TítúúbáCorrect

Explanation

Títúúbá (fífi ara ẹni sábẹ́ aláṣẹ) ń dènà ogun.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 62

Ẹni tí ó jẹ́ Olórí ogun Ilẹ̀ Yorùbá ni .....

  • A. Balógun
  • B. Àrẹ Ọ̀nàkakanfòCorrect
  • C. Aṣípa
  • D. Àrẹ-Àgò

Explanation

Àrẹ Ọ̀nàkakanfò ni olórí ogun ilẹ̀ Yorùbá.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 63

Àṣà Ìran –ara –ẹni –lọ́wọ́ tí ìgbàlódé ni ..........

  • A. Gbàmí-o-ràmí
  • B. Ẹgbẹ́ Alájẹ̀sẹ́kù
  • C. ÈṣúṣúCorrect
  • D. Àjọ dídá

Explanation

Èṣúṣú ni àṣà ìrànlọ́wọ́ ara ẹni (ààrẹ ìbílẹ̀).

Yoruba Language 2023 Objective — Question 64

Ewì alohùn tí ó wà fún Egúngún ni ....

  • A. Ìjálá
  • B. Ìyẹ̀rẹ̀
  • C. ẸṣàCorrect
  • D. Ẹsẹ ifá

Explanation

Ẹṣà (Ẹ̀ṣà Egúngún) ni ewì tí a fi ń kì Egúngún.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 65

Àwọn wo ni ó máa ń sin òkú ẹni àrá pa?

  • A. Ológùn –ún
  • B. Ọya
  • C. OnísàngóCorrect
  • D. Ọlọ́bàtálá

Explanation

Àwọn onísàngó (olùjọ́sìn Ṣàngó) ni ń sin òkú ẹni tí àrá pa.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 67

Bí a bá sọ pé " afọ̀n á gbó kó tó wò o"

  • A. Eléṣo là ń kí
  • B. Akọ̀pe là ń kí
  • C. Aboyún là ń kíCorrect
  • D. Ẹni tó ru eèso afọ̀n là ń bá wí

Explanation

Òwe ìṣírí fún aboyún.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 73

Parí òwe yìí "ẹni tó yá ẹgbẹ̀fà tí ò san" ..........

  • A. Ó ṣẹ́gi dínà egbèje
  • B. Kò ní rówó míìrán yáCorrect
  • C. Yó tètè rówó yá
  • D. Ó figi gún ibọ̀míràn

Explanation

Ẹni tó yá owó tí kò san kò ní rí owó míì yá.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 74

Ewo ni orúkọ àbíkú nínú àwọn wọ̀nyí?

  • A. ÀìnáCorrect
  • B. Àlàgbé
  • C. Dáódù
  • D. Daisi

Explanation

Àìná jẹ́ orúkọ tí a fi ń pe ọmọ tó ní ìbátan pẹ̀lú àbíkú.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 75

Odùgbèmí jẹ́ orúkọ ìdílé elẹ́sìn ..........

  • A. Ọya
  • B. Ọbàtálá
  • C. IfáCorrect
  • D. Ògún

Explanation

Odù jẹ́ ti Ifá; Odùgbèmí wà nínú ìdílé olùjọ́sìn Ifá.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 76

Nínú ewì Ọga ni Tíṣà kí akẹ́kọ̀ọ́ máa fi Tíṣà rẹ̀ ṣe yèyé jẹ́ wíwà.

  • A. Egún àti ìtapá sọ́rún niCorrect
  • B. Ìlẹ̀kẹ̀ ọwọ́ àti tẹsẹ sọ́rún ni
  • C. Aago ọwọ́ àti orúkọ wíwọ̀
  • D. Agbádá wíwọ̀ àti bàtà oyè

Explanation

Ewì sọ pé egún àti ìtapá sọ́rún ni ìwà àìbọ̀wọ̀ fún tíṣà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 77

Àwọn wo ni akéwì ń bẹ̀ láti gbé tíṣà sáàyè gidi?

  • A. Àwọn AláṣẹCorrect
  • B. Àwọn gbajúmọ̀
  • C. Àwọn Dókítà
  • D. Àwọn Adájọ́

Explanation

Àwọn aláṣẹ ni akéwì ń bẹ̀ kí wọ́n gbé tíṣà ga.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 78

Àwọn wo nínú àwọn Tíṣà ni akéwì pè ní Tíṣà gidi?

  • A. Ojúlówó tíṣà tí ó ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́Correct
  • B. Àwọn tíṣà tí ń kọ èdè Yorùbá
  • C. Àwọn tíṣà onímọ̀ ìgbàlódé
  • D. Àwọn tíṣà tí ń kọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀

Explanation

Tíṣà gidi ni ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí ó ti tọ́.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 79

Nínú ewì Ọ̀lẹ akéwì sọ pé " Ìyà mẹ́ta ló ń jẹ ọ̀lẹ" Ìyà mẹ́ẹ̀ta náà ni ..............?

  • A. Ìyà ọmọ, ìyà owó, ìyà iléCorrect
  • B. Ìyà ààrọ̀, ìyà ọ̀sán, ìyà àwọ̀lésùn à-jẹ-dààjìn
  • C. Ìyà ilé, ìyà ẹ̀kọ́, ìyà aṣọ
  • D. Ìyà oko, ìyà iṣẹ́, ìyà ọmọ

Explanation

Ọ̀lẹ máa ń rí ìyà ọmọ, owó àti ilé.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 80

Nínú "oore ló pé" ni Akéwì ti fi ewì gbani nímọ̀ràn àti ṣe ìkìlọ̀ pé tí a bá rẹ́ni tó ń ṣèkà sí wa ká..............

  • A. Ká ṣèṣan ìkà padà
  • B. Kí a má bá irú wọn ṣeré mọ́
  • C. Kí a máa fi oore dá ibi padàCorrect
  • D. Kí a bá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ jà

Explanation

Ewì "Oore ló pé" kọ́ wa pé kí a máa fi oore dá ibi padà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 81

Nínú ewì ẹ̀kọ́ dára, akéwì ní ẹ̀nìyàn tó fojú rénà ẹ̀kọ́ yóò di ..........

  • A. Lọ́ọ̀yà láwùjọCorrect
  • B. Dókítà láwùjọ
  • C. Olópàá láwùjọ
  • D. Ẹni èkò láwùjọ

Explanation

Ìtumọ̀ ewì ni pé ẹni tí ó kọ́ ẹ̀kọ́ yóò di ẹni ńlá láwùjọ.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 82

Ewì " Aláìgbọ̀ràn" ṣe ìkìlọ̀ pé ẹnití a wí fún tí kò gbà ń roko ..........

  • A. Ìgbéga
  • B. Ìbùkún
  • C. ÌparunCorrect
  • D. Ìyì

Explanation

Ẹni tí kò gbọ́ ìkìlọ̀ ń rokọ ìparun.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 83

Ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ̀ Olùkọ́ní ní ìlú Ayédé ni ........ ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Olùkọ́.

  • A. Táyé
  • B. Kẹ́hìndé
  • C. Kọ́lá
  • D. Jùwọ́nCorrect

Explanation

Jùwọ́n ni ẹni tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè olùkọ́.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 84

Nínú ìwé eré Onítàn "Ayé Olóore" Ìbáṣepọ̀ wo ni ó wà láàrín Jùwọ́n àti Amọ̀ọ́?

  • A. Ọmọ ẹ̀gbọ́n Amọ̀ọ́Correct
  • B. Bàbá Amọ̀ọ́
  • C. Akẹ́kọ̀ọ́ tí ó yá ilé gbé lọ́dọ̀ Amọ̀ọ́
  • D. Abúrò ìyàwó Amọ̀ọ́

Explanation

Jùwọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Amọ̀ọ́.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 85

Ọjọ́ kò le è ta, Ológbò rẹ kò lè peku jẹ, aṣá rẹ ò lè ta gìrì gbọ́mọ adìyẹ, bẹ́ẹ̀ ìwọ rẹ kò lè gbéja, jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu .....?

  • A. OjúlaríCorrect
  • B. Bọ́lánlé
  • C. Adùkẹ́
  • D. Baálẹ̀

Explanation

Ojúlarí ni olórí ìtàn tí ó sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 86

Níbo ni Ojúlarí ti dá ọ̀rọ̀ ọjọ́ sílè pé ẹsin inú ìwé ni ..........

  • A. Ọjà
  • B. Ilé ẹmuCorrect
  • C. Ilé ọjọ́
  • D. Afin Ọba

Explanation

Ilé ẹmu ni Ojúlarí ti dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 87

"Bí Obìnrin kò bá gbọ́rọ̀ sí ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, aburú òun ewu ńlá ló ń mú wá jẹ́ ọ̀rọ̀ ti ....... sọ nígbà ìgbẹ́jọ́.

  • A. Ológbẹ́nláCorrect
  • B. Ọ̀ṣúngbẹ̀jẹ́
  • C. Ṣíwọ̀ọkú
  • D. Orípélóye

Explanation

Ológbẹ́nlá ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà ìgbẹ́jọ́.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 88

Ẹnìyàn tó fún ọlọ́gbẹ́nlá ní idẹ ọ̀ṣun tí ó fi sọ́rùn ọmọ rẹ̀ ni ..........?

  • A. Olúṣọtan
  • B. Ọ̀ṣúngbẹ̀jẹ́Correct
  • C. Onígbàǹjo
  • D. Bílẹ́wú

Explanation

Ọ̀ṣúngbẹ̀jẹ́ ni ó fún un ní idẹ ọ̀ṣun.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 89

Ohun tí ó sọ Ọ̀ṣúngbẹ̀jẹ́ àti Onígbàǹjo ọkọ rẹ̀ di Ọlọ́rọ̀ ni..........?

  • A. Igi ọpẹ
  • B. Igi kòkóCorrect
  • C. Igi obì
  • D. Igi àgbọn

Explanation

Igi kòkó (cocoa) ni ó sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀: orúkọ ìwé "Ìdúró Gbàkòkò".

Yoruba Language 2023 Objective — Question 90

" Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wọlé, wèrè ni mo pè é pẹ̀lú aṣọ tó wọ sọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kìí wo wèrè ní tèmi" jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu ..........?

  • A. Wọ́lí OlúmilúàCorrect
  • B. Fọláwẹ́wọ́
  • C. Ọlálọmí
  • D. Pópóọlá

Explanation

Wọ́lí Olúmilúà ni ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 91

Ohun tí ó gbẹ́yìn Aarínọlá Iyàwọ Ẹniawífún tí ó pọ́n Ọkọ rẹ̀ lójú pẹ̀lú agbára òògùn ni ..........

  • A. Ó ya wèrèCorrect
  • B. Ó kú
  • C. Kò bímọ
  • D. Ó padà gba Ọlọ́run gbọ́

Explanation

Ó ya wèrè ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 92

Alaga àwọn ọlọ́kọ̀ sọ̀rọ̀ pé dandan ni ..........

  • A. Owó ìtaCorrect
  • B. Owó orí
  • C. Owó ọbẹ̀
  • D. Owó ẹrù

Explanation

Owó ìta ni àkọlé àti ohun tí wọ́n sọ pé dandan ni.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 93

Ẹgbẹ̀rún méje Náírà, Owó ......... ní dìí iṣẹ́ Tíṣà ni Dẹ̀jọ jẹ́ lérè lójó kan ṣoṣo.

  • A. Oṣù mẹ́ta
  • B. Oṣù méjì
  • C. Oṣù mẹ́rin
  • D. Oṣù kanCorrect

Explanation

Owó oṣù kan ni a ń pè ní owó iṣẹ́ tíṣà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 94

Òkèlè àkọ́bù nínú ìgbésí ayé Ọláoyè ni ..........

  • A. Ọmọlàbákẹ́Correct
  • B. Ọmọladé
  • C. Ọmọdení
  • D. Ọmọwùnmí

Explanation

Ọmọlàbákẹ́ ni òkèlè àkọ́bù.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 95

Nínú ìwé Lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ " Òkèlè Àkọ́bù" àwọn Ololùfẹ́ wo ni wọ́n mulẹ̀ láàrin ara wọn?

  • A. Bọ́lánlé àti Ọláoyè
  • B. Ọmọladé àti Dàda
  • C. Ọmọladé àti ỌláoyèCorrect
  • D. Tọ́lá àti Ìbùkún

Explanation

Ọmọladé àti Ọláoyè ni àwọn olólùfẹ́ náà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 96

Ẹ̀kọ́ tí ìwé Lítíréṣọ̀ " Òkèlè Àkọ́bù" Kọ́ wa ni pe ..........

  • A. Ó dára kí ènìyàn kàwé dójú àmìCorrect
  • B. Ó dára kí a máa mulẹ̀
  • C. Ọmọ ẹni máa ń fẹ́ràn ẹni
  • D. Iṣẹ́ àgbẹ̀ dára

Explanation

Ìwé náà kọ́ wa pé kí ènìyàn kàwé dójú àmì.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 97

Ọ̀rọ̀ ọlọ́run sọ pé ' Aláàánú ......

  • A. Aláàánú yóò rí ìyà he
  • B. Aláàánú yóò rí ẹ̀wọ̀n he
  • C. Aláàánú yóò rí owó he
  • D. Aláàánú yóò rí àánú gbàCorrect

Explanation

Aláàánú yóò rí àánú gbà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 98

Lára Ẹ̀kọ́ inú ìwé Lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ " Ojúlópẹ́sí ni ..........

  • A. Ìwé kíkà dára
  • B. Ó dára kí obìnrin fẹ́ran ọkọ rẹ̀
  • C. Ẹ̀ṣan kò gbógun, ẹ̀ṣan á kéCorrect
  • D. Ó dára kí ènìyàn bímọ púpọ̀

Explanation

Ẹ̀san kò gbógun, ẹ̀san á ké: ẹ̀kọ́ ìwé náà.

Yoruba Language 2023 Objective — Question 99

Ta ni ẹni tó lo agbára iná láti inú omi tí ó já okùn tí Àṣàkẹ́ so mọ́ ọrùn lórí igi láti pokùn so.

  • A. ỌládùnCorrect
  • B. Àdùkẹ́
  • C. Adémọ́lá
  • D. Arẹ̀wà

Explanation

Ọládùn ni ó fi agbára iná omi já okùn náà.

Advertisement

Sign up free to unlock

  • Score tracking
  • Practice history
  • Saved questions
  • Progress dashboard
  • Personalized sessions
  • Weak-topic breakdown

…and/or go further with premium services and No Ads.