Free account: track your progress — Sign up free

JSCE Yoruba Language 2023 Objective — Question 6

Question 6 of 100 from the Junior Secondary Certificate Examination (JSCE) Yoruba Language 2023 Objective paper, with the correct answer and a full explanation.

Advertisement

ÀKÀYÉ EWÌ: Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, Ìyá mi máa ń fú mi ní wàrà, Bàbá mi a sì máa fi ṣíbí fún mi lóúnjẹ. N kò mọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀, Tí wọ́n fi ń ṣe ìtọ́jú yìí fún mi, Ṣùgbọ́n nígbà tí mo dàgbà, Ìyá mi ń retí kí n wá Ṣanjó, Bàbá mi fẹ́ kí n fi ṣíbí tọ́mi sóun lẹ́nu. Ìgbà náà ló tó yé mi Kedere pé, Bíbọ́ tí wọ́n ń bọ́ mi nígbà èwe, Nítorí ọjọ́ ogbó wọn ni. Nítorí bókété bá dàgbà tán, Ọmú ọmọ rẹ̀ ni yóò máa mu. Nítorí ká lè rẹ́ni ké sí, La fi ń tọ́jú ọmọ. Nítorí ká lè rẹ́ni fẹ̀yìntì, La fi ń mójú tọ́mọ. Kò ṣẹ́ni tó mọ ìdí òjò, Bí ò ṣe Ṣàngó. Kò ṣẹ́ni tó mọ ohun tómele ń wí, Tó ju ẹni tó gbómele lọ́wọ́ lọ. Kò ṣẹ́ni tó mójú ọwá, Tó ju ẹyin lójú ọwá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni kò ṣẹ́ni tó lè mọ̀ ọ́n-pọ̀n, Tó yàtọ̀ sí ọlọ́mọ. Edùmàrè jẹ́ a rọ́mọ tọ́jú ẹni, Nítorí ọmọ ní í róni tó ju aṣọ lọ. Ṣanjó tí akéwì mẹ́nu bà nínú ewì yìí túmọ̀ sí ..............

  • A. Owó
  • B. Oúnjẹ
  • C. Ìtọ́júCorrect
  • D. Oko

Explanation

Ìyá ń retí kí ọmọ wá ṣe ìtọ́jú òun; ìtumọ̀ ni ìtọ́jú.

Advertisement

Sign up free to unlock

  • Score tracking
  • Practice history
  • Saved questions
  • Progress dashboard
  • Personalized sessions
  • Weak-topic breakdown

…and/or go further with premium services and No Ads.